Ijoba ipinle Osun ti ki oselu bọ eto-ẹkọ o - Awon eeyan iwo-oorun Osun ke gbajare


Awon olugbe agbegbe Iwo-oorun Osun ti ke si gbogbo awọn abiyamo tooto ti won mo pataki eto eko gba won lori igbesẹ tijoba ipinle Osun gbe lati da eto-ẹkọ ọfẹ lenu isinmi tawon akekoo agbegbe naa maa n se duro.

Lati odun merin seyin ni ajọ kan to n je ALAAFIA DOTUN eleyii ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi nsagbateru rẹ ti maa nseto ẹkọ-ọfẹ fawon akekoo ninu ọlude, eleyii to mu ki ipo ẹkọ lawon agbegbe naa muna doko sii

Ọmọọba Babayẹmi wa ninu ẹgbẹ oselu APC ni gbogbo asiko yen, ko si si wahala kankan rara, sugbon ni kete ti okunrin naa bọ sinu egbe oselu PDP ni oniruuru igbesẹ ti n waye lati dawọ ohun gbogbo to n se duro.

Ọkan lara awon agbenusọ fawon eeyan ilu Gbongan, Alhaji Ojewale salaye pe ko si obi ti inu re ki i dun si eto naa latigba to ti bẹrẹ nitori pe ajọ naa ko fi ti egbe oselu kankan se rara.

O ni gbogbo eto ni won tun ti la silẹ fun ti olude yii, koda, eto-ẹkọ ọfẹ naa ti bere lawon ibugbe mejidinlogbon ti won ti fee se e kaakiri ekun idibo naa ko too di pe iwe kan wa lati ileese to n ri si eto ẹkọ nipinle Osun pe ki won dawo duro.

O ni awijare ti won kọ sinu leta naa jọ gbogbo awon obi loju patapata, "Se ni won so pe ijoba fee tun awon yaara ikawe ti won ti n kekoo se. Ibeere ti a wa n beere ni pe se wpn ko mọ ko too di pe won fun awon alakoso lanfaani lati lo ibe tele?

"Omo egbe oselu APC ni mi, sugbọn gbogbo eleyii ko sele lasiko ti Babayemi wa ninu egbe wa, oro ẹkọ awon omo ki ise nnkan to yẹ kijoba ki oselu bọ rara. Gbogbo wa la janfaani eto yii gege bi obi latigba to ti bere.

"Niwon igba ti ajọ naa ko ti beere iranlowo kankan lowo ijoba latigba to ti bere, ko si idi kankan to fi ye ki won da eto naa, ninu eyi to jẹ pe awọn akẹkọọ bii ẹgbẹrun mẹrin ni wọn ti janfaani lati lo kawe ni yunifasiti nipase ajọ yii duro rara".

Awon eeyan yii wa rọ Gomina Oyetola lati tun ero re pa lori igbese naa, ki awon si maa ba ẹkọ naa lo fun ose bii meta to ku ki olude pari.

No comments:

Post a Comment