EID-EL KABIR: Ẹ ṣawokọṣe igbeaye ojiṣẹ-Ọlorun Ibrahim - Babayemi


Pelu bi awon musulumi jakejado orileede yii se n se ayeye odun Ileya loni, Omooba Dotun Babayemi ti ro won lati ri igbesi aye irele, ife ati ibagbepo alaafia to farahan lara ojise-Olorun, Ibrahim, gege bii awokose.

Ninu oro ikini ku odun re si awon musulumi nipinle Osun, paapaa, niha ẹkun Iwo-Oorun Osun lo ti parowa yii.

Babayemi, oloselu lati ilu Gbongan ọhun woye pe ilana eko Id-el-Adha eleyii to da lorii nini igbagbo ninu Olorun ati gbigbekele ife Re gbodo maa jeyo ni gbogbo igba ninu aye awon elesin Islam.

O ran won leti pe ki i se agbo ti won pa lojo odun tabi eran ti won je lo ni nnkan se pelu Olorun bikose atunhu iwa ati titun igbeaye won yewo.

Babayemi ro won lati mu ife si Allah ati igbagbo ninu Re lokunkundun, ki won si nawo ife yii kan naa sawon alajogbe won nipase eyi ti idagbasoke yoo fi wa nipinle Osun.

No comments:

Post a Comment