Arabinrin Mercy Ayodele, eni to je oludije funpo gomina ipinle Osun labe egbe oselu Restoration Party (RP) ti seleri pe mimu irorun ba igbesi aye awon obinrin pelu awon odo ni yoo je opo pataki tisejoba oun yoo duro le.
Lasiko ti obinrin oloselu yii loo gba foomu idije ni olu-ile egbe RP nilu Osogbo lo ti ni etan ati iro ti po ju ninu egbe oselu APC ati PDP lorileede yii eleyii to ni o ti mu kawon araalu soreti nu ninuu won.
Ayodele fi kun oro re pe imupadabosipo ni ise ti oun waa se nipinle Osun nitori gbogbo nnkan ti isejoba egbe oselu APC ati PDP ti won ti sejoba nipinle Osun ti baje loun fee tun se.
Gege bo se wi, eto ilera to kunju osunwon yoo wa fawon obinrin ati odo, nigba ti oun yoo mu eto eko to duroore lokunkundun nitori nipase eleyii ni ireti yoo fi wa fawon odo ti won je ojo ola ipinle yii.
O waa ro gbogbo awon iyalomo l'Osun lati ri oun gege bii araa won, ki won si fi ibo won gbe oun wole gege bii obinrin lasiko idibo ojo kejilelogun osu kesan ohun pelu ileri pe oun ko nii ja won kule.
Alaga egbe oselu naa l'Osun, Pasito Tosin Odeyemi lo asiko naa lati ke si gbogbo awon omo egbe RP kaakiri ipinle Osun lati bere itaniji lori idi tawon araalu fi gbodo dibo fun oludije latinu egbe oselu RP.
No comments:
Post a Comment