Idibo awon akekoojade: PAV fee wo UNIOSUN lo sile ejo


Egbe kan ti ko rogboku lejoba, People's Advocacy Vanguard (PAV) ti kilo fun awon alase ile eko giga UNIOSUN lati yago gedegbe si oro to ba nii se pelu egbe awon akekojade nileewe naa.



Ni pataki julo, PAV so pe otubante ati ofo ojokeji oja ni idibo kangaru kan ti egbe akekoojade ile eko naa se laipe yii ninu eyi ti won ti kede enikan to n je Aboderin Olumuyiwa Aduragbemi gege bii eni to jawe olubori.

Ninu atejade kan ti akowe alukooro egbe naa, Ogundele Babatope fowo si lo ti di mimo pe ona meji otooto ni Aduragbemi fi huwa tako abala keedogun ofin egbe naa eleyii to mu un padanu anfaani to ni lati dupo tabi di ipo kankan mu ninu egbe akekoojade ile eko naa.

Ogundele ni lasiko iforowero kan to waye laarin Ogbeni Aduragbemi ati igbimo alase (BoT) UNIOSUN pelu akowe ileewe naa lo ti so pe oun je Facility manager and business development manager ni Transport Infrastructure, Engineering and Procurement Organization ti gbogbo eeyan mo si Planet Project Ltd nipinle Eko.

PAV ni awon ti sewadi daadaa, awon si ti rii pe iro funfun balau ni, Aduragbemi kii se nnkan to so pe oun je.

Bakan naa ni won ni gbogbo awon owo to ye ki Aduragbemi san gege bii omo egbe ni ko san sapo egbe to fi dibo, eleyii to tako agbekale egbe lori enikeni to ba fee dije.

Won  ni ti awon alase pelu awon omo ajo yo seto idibo naa ko ba fagile esi idibo ohun laarin ojo meje, ile ejo ni yoo ba awon yanju oro naa.

No comments:

Post a Comment