Oludije fun ipo ile igbimo asofin apapo orileede yii lati agbegbe Irewole, Ayedaade ati Isokan, Onorebu Taiwo Oluga ti ki Ooni Ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi ku oriire ayeye ojoobi odun kerinlelogoji lori eepẹ.
Oluga ni ipa manigbagbe ni Ooni Ogunwusi n ko lori bi isokan ati ife yoo se wa laarin awon omo Yoruba kaakiri agbaye, o si ti sọ ọ di aayo laarin awon lobaloba lorileede yii.
O ni igbelaruge asa ati awon nnkan abalaye, eleyii to je Oba Ogunwusi logun ti ta kabiesi naa yọ, ati pe laipẹ ni awon nnkan naa yoo bere sii so eso rere.
Oluga gbadura fun emi gigun ati ilera pipe fun Oba Ogunwusi, eni to sapejuwe gege bii aayo fun ile Yoruba.
No comments:
Post a Comment