Igbese Aregbesola yii ko seyin bi awon alatileyin re se n so fun un pe o see se ki wahala wa lori oro eni ti yoo gbapo lowoo re.
Bo se wu gomina lati gbe ipo fun eni ti yoo gboran sii lenu naa la gbo pe awon omo egbe oselu APC l'Osun naa n leri pe awon ko nii gba fun un.
Idi niyii, gege bi a se gbo lagbala iroyin, ti gomina fi bere ifikunlukun pelu Otunba Omisore toun je omo egbe oselu PDP ti gbogbo won si nigbagbo pe o see se ki won gbe sile legbe naa fun idije gomina.
Gege bi enikan to sunmo gomina sugbon to ni ka foruko bo oun lasiri se so, se ni Aregbesola pinnu pe kaka ki eku ma je sese, se lawon yoo fi oro naa sawadanu.
O ni gomina ni ti awon omo egbe APC l'Osun ba fi le dite oludije toun ba fowosi, ti won ko si je ko wole nibi idibo abele, se loun yoo kuku yatan, ti ipo naa yoo si bo sowo egbe alatako.
Idi niyii to fi n wa eni to see se kawon egbe alatako to loruko julo nipinle Osun lo lati jo dunadura ko too di asiko naa.
No comments:
Post a Comment