Iwo-Oorun Osun la ti fe gomina, ko si gbodo je agbalagba - Oyinlola

Gomina ipinle Osun tele to tun je asaaju ninu egbe APC, Omooba Olagunsoye Oyinlola ti so pe laini si iyanje tabi ojusaju, iha Iwo-Oorun Osun ni ipo gomina to si bayii.




Lagbala iroyin la ti fi to yin leti tele pe laipe ni Oyinlola yoo so erongba re lori aheso pe o fee dupo gomina.

Oyinlola ni bo tile je pe opolopo awon lookolooko nipinle Osun ni won ti wa ba oun pe koun tun jade dupo gomina sugbon oun ko ni dupo naa bikose ki oun ti enikeni to ba fee dupo leyin.

O ni asiko fifi agbalagba olopolo analoogi je gomina ti koja, idi niyen to fi daba pe eni ti yoo ba je gomina tawon araalu too gbadun ko gbodo ju omo aadota odun lo.

O ni aye imo ero la wa yii, awon ti won ba ti dagba gbodo fi ipo oselu sile fawon odo ti won si jafafa ti won si lafojusun lori oro isejoba.

Omooba Oyinlola ni erongba awon agbaagba ti won ja fun igbekale ipinle Osun ni lati rii pe gbogbo ekun meteeta ni won lanfaani si ipo naa, ko si gbodo si iyanje.

Nigba igba ti Aaringbungbun Osun ti lo Odun mokanla ataabo, Ila Oorun Osun ti lo odun mejo, Iwo Oorun Osun lo kan Lati fa gomina kale fun eto idibo osu kesan, gege bi Oyinlola se so.

No comments:

Post a Comment