Gomina ipinle Osun, Ogbeni Adesoji Aregbesola ti ni awon osise ijoba nipinle Osun ni won duro gege bii ejiká ti ko je ki aso ye lorun oun pelu ifarada ati ife ti won ni sisejoba oun.
Lasiko ti Gomina n si oju ona alabala meji to lo lati Oríta Olaiya si Ita-Olookan nilu Oṣogbo ni Gomina ti so pe ipamora ati agboye nla lawon osise fi han si oun lasiko ti nnkan daagun funpinle Osun.
O ni idi niỳen toun fi fi oruko awon osise so oju ona naa, iyen Workers' Drive lati le fi emi imoore han sawon osise ohun.
A oo ranti pe lati nnkan odun meji ataabo seyin lawon osise ijoba nipinle Osun ti n gba idaji owo osu, ti gomina si n seleri fun won pe ti eto oro aje orileede yii ba ti rugogo sii lawon osise naa yoo bere sii gba ekunrere owo osu.
Aregbesola, eni to di ebi bi ko se rowo sejoba ru egbe oselu PDP to gbejoba fun un salaye siwaju sii pe oju ona ti won si naa yoo tubo mu ki eto oro aje ipinle Osun tun so rura si.
No comments:
Post a Comment