Asofin to n soju awon eeyan iha Ariwa Ife nile igbimo asofin Osun, Onorebu Tunde Olatunji ti sapejuwe Igbakeji aare orileede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo gege bi asiwaju to see tele.
Ninu oro ti Olatunji fi ranse lati ki Osinbajo ku oriire ojobi re lo ti ni amuyangan ni ojogbon naa je nipa ijafafa lenu ise.
Olatunji ni Osibajo je eni to see fokantan ati olotito eniyan to ma n fe lati ran awon eeyan lowo laika ti eya tabi esin si.
O wa gbadura pe ki Olorun tubo kun Ojogbon Osinbajo fun ogbon ati imo pelu ilera to peye.
No comments:
Post a Comment