Iku doro! Osere tiata Yoruba miin tun ti ku o




Ajalu nla miin tun ja lu awon osere tiata Yoruba orileede yii loni ojo kinni osu kefa pelu bi okan lara won, Motunrayo Adeoye se jade laye.


Aisan 'majata' (ulcer) la gbo pe mama agba to maa n fi itara sere yii n ba finra lati odun die seyin ko too di pe o pada jade laye loni.

Won ti sinku obinrin, eni to je molebi Alaafin ti Oyo, Oba Lamidi Olayiwola naa si ile re to wa ni Akobo Ojurin nilu Ibadan.
Osogbo Technical College nipinle Osun lo ti keko nipa awon nnkan elo inu ile (Electronics) ko too lo keko sio lorileede Switzerland.

Odun 2010 ni iya yii feyinti lenu ise oba nile igbohunsafefe ti BCOS, leyin naa lo darapo mo awon osere tiats daada.

No comments:

Post a Comment