Ajumọṣe ni iṣẹ atunṣe orilẹede yii - Ademọla Adeleke


Seneto to n soju awon eeyan ekun Iwo-oorun Osun nile igbimo asofin agba orileede yii, Ademola Adeleke ti so pe ojuse tolori-telemu ni lati rii pe nnkan padabosipo ni Naijiria.




Ninu oro ayajo odun kokandinlogun ijoba tiwantiwa lorileede yii ni asofin yii ti so pe wahala awon akoni ti won ja fun ominira orileede yii ati tijoba tiwantiwa ko gbodo ja si asan.

Gege bo se wi, "̀loooto ni nnkan ko rorun lasiko yii, paapa pelu bi oro-aje se n denukole lojoojumo, sibe, a ko gbodo kawo gbera, a gbodo se ojuse tiwa naa lati ru ireti ojo-ola to dara soke fun orileede yii.

"Gbogbo wa la ti rii bayii pe ko si nnkan ti a le fi ijoba tiwantiwa we, idi niyen ti a fi gbodo daabo bo o, ki a si yago patapata fun igbese to le da omi alaafia orileede yii ru.

"Opolopo emi lo ti sofo laye ijoba ologun, a ko gbodo je ki igbiyanju won lo lasan, a gbodo rii pe orileede yii n te siwaju labee bo ti wu ko ri, a ko ni orileede miin, Naijiria yii nikan ni tiwa".

No comments:

Post a Comment