Idibo to n bo yii ni yoo so bi ojo iwaju egbe wa atipinle Osun yoo se ri - Fatai Akinbade
Awon adari egbe oselu PDP nipinle Osun ni won ti ro lati lo ogbon Olorun lori ona ti won yoo gba mu eni ti yoo je oludije latinu egbe naa fun idibo gomina ojo kejilelogun osu kesan odun yii.
Lasiko abewo ti okan lara awon oludije, Alhaji Fatai Akinade Akinbade se sawon eeyan Ejigbo, Egbedore ati Guusu Ede lo ti salaye pe asiko to gbege gidigidi niyii, o si nilo ki awon adari egbe PDP l'Osun ronu daada lori igbese ti won ba fee gbe.
O ni o rorun fun Omooba Oyinlola Olagunsoye lati le Oloye Bisi Akande lodun 2003 nitori pe Oloye SM Afolabi pelu awon agbaagba yooku nigba naa fi ogbon inu to oro naa ti ko si si wahala.
Akinbade ni ojoowaju egbe oselu PDP wa ninu igbese egbe PDP lasiko yii, bee ni ireti awon eeyan ipinle Osun ga pupo ninu egbe oselu PDP nitori egbe ohun nikan lo le yo won ninu iya ati iponju ti won wa yii.
Akowe agba funjoba ipinle Osun lasiko isejoba Omooba Oyinlola naa so siwaju pe iriri oun fun aimoye odun nidi oselu ti je ki oun mo nipa isejoba, bee loun si ni oye ati agbara lati dari ipinle Osun.
O ni ko si ooto ninu aheso to n lo kaakiri pe oun ko lee ri owo sepolongo ibo nitori ko si eni to maa n kọ owo si iwaju ori, bee loun si ti joko sesiro nnkan ti yoo na oun, oun si ti setan lati gbe igbese akin ohun.
Akinbade waa ro gbogbo awon oludije lati gba alaafia laaye saaju asiko idibo abele naa nitori enikansoso naa ni egbe yoo fa kale lati koju awon oludije latinu egbe oselu to ku.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment