Enjinia Adelere Oriolowo ti so pe bii igba teeyan kan fee mo on mo da wahala sile ni ti oludije kankan ba tun dide lati iha Ila-Oorun tabi Aaringbungbun ipinle Osun lati dupo gomina to n bo lona yii.
Oriolowo, eni to je omobibi ilu Iwo, toun naa si n gbaradi lati gba ipo ohun lowo Gomina Aregbesola salaye fawon oniroyin pe ti ko ba nii si iyanje tabi ojusaju nibe, iha Iwo-Oorun Osun ni oro ipo gomina kan.
O ni yala o wa ninu akosile tabi ko si lakosile, iha Iwo-Oorun nikan ni ko tii lanfaani bii ti awon to ku lati se gomina l'Osun ati pe gbogbo ona ni oun si fi kunju osunwon lati di ipo ọhun mu.
Oriolowo, eni to je alakoso O'Ramp so siwaju pe ise ribiribi ti Gomina Aregbesola ti se nipinle Osun koja eyi ti enikan ti ko nimo kikun nipa aato ilu le daya kọ ati pe bii igba teeyan fee fa owo aago idagbasoke ipinle Osun seyin ni ti eni ti kii se omo egbe oselu APC ba loo wole ninu idibo naa.
Gege bo se wi, oniruuru iriri loun ti ni nipa bi a se n sakoso awon eeyan ati bi a se n lo ogbon inu lati le ri pe alaafia joba kaakiri, awon nnkan wonyii ni won si mu oun tayo awon oludije to ku ninu egbe oselu APC.
Oriolowo waa ro awon araalu lati tubo gbaruku tisejoba Ogbeni Rauf Aregbesola niwonba igba to ku yii, ki won si mo pe itesiwaju ti ko legbe ni yoo tun ba ipinle ti anfaani ba le wa fun oun lati di gomina.
No comments:
Post a Comment