Egbe oselu PDP lo sakoba fundagbasoke ijoba tiwantiwa lorileede yii - Moshood Adeoti
Okan pataki lara awon oludije funpo gomina ipinle Osun labe egbe oselu APC, Alhaji Moshood Adeoti ti ni ifaseyin nla nisejoba olodun merindinlogun ti egbe PDP se mu ba orileede Naijiria.
Ninu oro ayajo ojo demokresi ti akowe iko ipolongo re, Moshood Adeoti Campaign Organization (MACO), Kayode Agbaje fi sita lo ti ni ko to si egbe oselu PDP lenu lati maa soro alufansa si ijoba Aare Buhari nitori pe awon gan an leku eda to da opolopo wahala sile lorileede yii.
Adeoti, eni to je akowe funjoba ipinle Osun lowolowo ni loooto ni iyato ti n ba oniruuru nnkan lorileede yii sibe, ijoba si nilo adura ati aduroti awon araalu lati yanju gbogbo nnkan to ti baje.
O ni ijoba tiwantiwa yoo rese wale ti tolori telemu ba le gbiyanju lati maa se nnkan to to nigba gbogbo, ti ko si si iyanje tabi ojusaju nibi gbogbo lorileede yii.
Adeoti waa ro gbogbo awon eeyan ipinle Osun lati fi ibo won gbe oun wole nigba ti asiko ba to, ki gbogbo eni ti ko ba si tii gba kaadi idibo lo se bee ki won le lanfaani lati yan eni to to sipo gomina ipinle Osun.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment