Eyi ni bi owo se te Alao to fi Khadija omo igbakeji Mimiko soogun owo l'Akure


iroyin, isele nla

Ileewe girama ni Khadijat Oluboyo ati Adeyemi Alao ti koko bere ere-ife, sugbon won ko gburo ara won mo leyin ti Alao koja silu Abuja nibi to n gbe.

Leyin ti Khadija wo yunifasiti Adekunle Ajasin ti ilu Akungba Akoko ni oro ife won tun wo pada, ti Alao, eni ti inagije re n je QS tun bere sii wolewode pelu Khadija omo Alhaji Lasisi Oluboyo to je igbakeji gomina ipinle Ondo tele, Dokita Mimiko.

Lojo Sannde to koja la gbo pe Alao so pe ki Khadija wa ki oun nile lagbegbe Oke-Aro nilu Akure, omobinrin naa si lo sibe sugbon alo Khadija ni won ri, ko seni to ri abo re.

Lojo kefa ti Khadija di awati la gbo pe oku re dede yo si okan lara awon aburo Alao ninu ile, idi niyen ti onitohun fi bere sii wa vbogbo yara lati mo nnkan to n sele.

Iyalenu lo je faburo Alao nigba to ba oku Khadija labe beedi Alao, o pariwo sita, oro naa si di ti olopaa, bee ni won mu Alao.

Gege bi a se gbo, ojo meje ni babalawo so pe ki Alao fi toju oku Khadija pamo sabee beedi ki ise le dahun daadaa, sugbon ojo kefa lasiri tu.

Alukoro ileese olopa ipinle Ondo, Femi Joseph fidi isele naa mule, o si seleri pe komisanna yoo ba awon araalu soro lori e leyin iwadi kikun.

No comments:

Post a Comment