Esin funfun gbera! Faforiji di alaga egbe oselu SDP l'Osun

iroyin/oselu

Egbe oselu Social Democractic Party (SDP) nipinle Osun ti kede Dokita Bayo Faforiji gege bii alaga won.


Lasiko idibo abele to waye lopin ose to koja ni gbogbo awon asoju (delegates) ti won leto lati dibo fenuko, ti won si yan Faforiji gege bii alaga won laisi atako kankan.

Ninu oro re, Faforiji dupe lowo awon asoju naa fun ife ti won fi han sii, o ni okan oun bale pe didun losan yoo so fun egbe naa niwon igba ti awon ti jagun awon alatako, ti awon si ti segun.

Faforiji ro gbogbo awon omo egbe lati san sokoto won giri, ki won si rii pe egbe naa gbakoso ijoba ipinle Osun lowo Gomina Aregbesola ninu idibo to n bo yii.

O ni goolu egbe naa ti la ina koja, eleyii lo si so o di aayo fun gbogbo awon eeyan ipinle Osun bayii nitori pe gbogbo egbe oselu ti won ti dan wo lo ti ja won kule.

Gege bo se wi, "ko si asiko kankan fun wa mo ti a le fi sofo rara, aaya wa ti be sile, o be si ise ni o, a ko gbodo ja awon eeyan kule nitori awon araalu fokan tan wa pupo, mo si mo pe a maa ki ara wa ku oriire leyin idibo gomina ti a fee se yii"

No comments:

Post a Comment