Ọṣun 2018: Ẹlẹtan ati ọlẹ lawọn to n pariwo 'West lo kan' - DAG


Egbe Development Advocacy Group (DAG) ti bu enu atẹ lu iwọde tawon kan se nilu Osogbo lose to koja, o si sapejuwe igbese naa gege bi eyi to kun fun etan.


Ninu atejade kan ti akowe ipolongo egbe naa, Comredi Wasiu Ibraheem fi sita, o ni awon ọlẹ oloselu ti won ko mo ju tara won lo ni won wa nidi iwode naa.

DAG ni ohun to ye ko mumu laya gbogbo awon ti won nife ise rere ti Aregbesola se l'Osun ni bi won yoo se sise papo pelu enikeni to ba kunju osunwon ipo naa.

O ni ko si oloselu kankan to fe itesiwaju ipinle Osun to le maa ba won pariwo pe ibikan lo kan ati pe pupo ninu awon ti won wa nidi iwode etan naa ni won je oloselu ti won ko ni ipa kankan lori awon eeyan won latigba ti won ti n soselu.

Gege bi atejade naa se wi, 'o pon dandan ka tete fopin si oro alufansa tawon kan n so kaakiri. A gbodo yago fun ohunkohun ti ko si ninu ofin egbe wa, ti ko si si ninu iwe ofin orileede wa.

'Awon ti won wa nidi ariwo "West lo kan" fee da wahala sile nipinle Osun ni, kii se wi pe won ni ife awon eeyan won lokan, awon yen naa ni won maa n ki oro esin bo gbogbo nnkan, ti ko si ye ko ri bee.

"To ba je pe won nife araalu ni, ariwo "Best lo kan" lo ye ki won maa pa, kii se"West lo kan".

DAG waa ro awon araalu lati mase faaye sile fun awon anikanjopon oloselu lati da wahala sile l'Osun, ki onikalulu awon omo egbe APC si dibo fun eni to kunju osunwon lasiko idibo piramari egbe ohun.

No comments:

Post a Comment