Idibo 2019: Egbe SDP sadehun atileyin fun Omooba Dotun Babayemi

Bi ojo idibo sile igbimo asofin agba orileede yii se n sunmọle naa ni imole n tan si aseyori Omooba Dotun Babayemi, eni to n dije lati soju awon eeyan agbegbe Iwo-oorun Osun nilu Abuja.

Bi awon omo egbe oselu Action Democratic Party (ADP) to je egbe  Babayemi, se n fojoojumo seleri atileyin won fun un, naa lawon omo egbe oselu mi-in ti won n gbe lagbegbe naa n so pe kii se oro egbe oselu nidibo to n bo yii, Babayemi nikan nipo naa tọ si.

Awon omo egbe oselu Social Democractic Party (SDP) ko kan tie fi oro naa bo rara, won ni ko si oloselu miin to kunju osunwon ise naa ju Babayemi lo, won si so pe oun lawon yoo dibo fun lojo kerindinlogun osu keji odun yii.

 Fọfọ ni ori papa isere ileewe St Anthony School, lagbegbe Oke-Bode nilu Iwo kun lopin ose to koja nibi eto asekagba idije boolu ti won pe ni Prince Dotun Babayemi Youth Football Competition, eleyii to waye laarin awon egbe agbabolu niha Iwo-oorun Osun, nibi ti Rovet FC tilu Iwo ti fagba han Hon.Shakor FC tilu Ede pelu ami ayo meta si odo.

Awon omo egbe oselu SDP lo asiko idije naa lati fidi atileyin won mule nita gbangba fun Omooba Babayemi. Igbakeji alaga egbe oselu naa nipinle Osun, Ogbeni Folaranmi Hamzat lo obitibiti awon omo egbe naa sodi lọ sibẹ.

Folaranmi ni ko si nnkan tawon ri lara Babayemi ju iwa otito, eyi to se fokantan ati pe lẹyin ti awon yen ipile awon oludije to ku wo, Babayemi nikan lo kunju osunwon lati soju nile igbimo asofin agba orileede yii.

O lo asiko naa lati parowa fun gbogbo awon eeyan agbegbe ọhun lati fowosowopo pelu Dotun Babayemi lori erongba re, bee ni won gba awon ti ori ṣẹgi ọla fun lorileede yii lati fi Babayemi sawokose nitori pe aimoye awon onirobinuje okan lo ti dun ninu.

Gbogbo awon agbaagba ti won soro nibe ni won so pe laisi ariyanjiyan kankan rara, Omooba Babayemi yoo tayo awon oludije to ku nibi idibo osu keji ohun.

Won salaye pe ko si eka igbe aye kankan ti Babayemi ko fowokan ninu aye tolori-telemu nibe laika ti egbe oselu tabi esin si rara, bo se sise ribiribi leka eto ilera, lo ran ọpọ omo lowo lenu eko won, bee ni awon elesinjesin je anfaani Babayemi, o si daju pe yoo te siwaju to ba le de ipo giga naa.

Asaaju egbe oselu ADP lorileede yii, Alhaji Moshood Adeoti lo ko awon omo egbe oselu ADP sodi lo sibi eto naa, bakan naa ni egbe akoroyin ere idaraya ti eka ipinle Osun fun Babayemi ni ami-eye fun atileyin re lori nnkan to nii se pelu ere idaraya nipinle Osun.
Awon alakoso egbe oselu Social Democratic Party (SDP) ti won wa nibi eto naa lati fontẹ lu Babayemi ni alaga won niha Iwo-oorun Enjinia Adetoye Ogungboyega, olori awon obinrin lagbegbe naa, awon alaga nijoba ibile Ayedaade (Hon Ojo Kamorudeen Elegunmeje), Ayedire (Alhaji Hon. Abideen Amusan), Iwo (Hon Alhaji Akande Akeem), Ede North, Ede South (Alhaji Nureni Durodola Afebioye), Egbedore (Alhaja Isiaka Amina) ati Ejigbo (Hon. Oloyede Odunayo).

No comments:

Post a Comment