Awon soja o le kapa Boko haraamu lorileede yii, afi ti awa ọlọdẹ ba da si - Ọdẹtọdẹ
Aarẹ egbe ọdẹ nipinle Osun, Oloye Hammed Nureni ti so pe se lawon ologun orileede yii kan n gbiyanju lasan lori oro ikọ boko haraamu ti wọn n fojoojumo yọ orileede yii lenu, ko si bi agbara won se le kawọ won, ayafi tijoba ba sise papo pelu awon ọlọdẹ.
Nibi eto kan ti egbe naa se nilu Osogbo, laipe yii ni aare won, eni ti gbogbo eeyan mo si Ọdẹtọdẹ, ti ni idi to fi dabi eni pe ọrọ ikọ asekupani ohun n di ojoojumọ bii ẹkun apọkọjẹ ko ṣẹyin bo se je pe ilana ẹkọ awon ologun ko fun won lagbara lati wo kọrọkọndu ibi tawon ikọ naa n farapamo si.
Oloye Nureni so siwaju pe, "a bi awa olode sinu ise wiwonu igbo tosan-toru ni, a si mo oniruuru iriri ti a maa n ba pade ninu igbo, eko lasan lawon ologun gba,o yato si abinibi, tijoba ba le sisẹ po pelu wa, eyin naa a ri i pe isinmi ati ifokanbale yoo ba wa kaakiri orilẹede yii.
"A ti setan lati ti awon agbofinro leyin lori ipese eto aabo fun emi ati dukia awọn araalu lati alẹ digba ti ile ba mọ, idi niyen ti a fi n ke si awon ijoba lati sedanilekoo fawon omo egbe wa lori ona eto aabo to ba ti aye ode oni mu.
"Lati le mu ki iee yii rorun fun wa, a nilo ọkọ nla to se e gbe wonu igbo kaakiri, ko sibi ti a ko le de ti ọkọ to dara ba ti wa, ko si si asiko ti a kẹẹfin awon odaran nibikibi ti a ko nii lo kiakia.
"Inu igbo ni awon ọbayeje yii ti n pile opolopo iwa aburu ti wọn n hu lawujo wa, opo igba ti a ba degbe lo la maa n ṣalabapade ibuba awon onijibiti, ti awon agbenipa, ibuba awon odaran, ibuba awon elegbe-okunkun, idi niyii ti a fi n ke sijoba pe ki wọn je ka pada sigba iwase.
"A ti lo ọgbọn-ori eeyan nipase awon ologun, sugbon kaka kewe agbon wahala yii dẹ, lile lo n le si i, obitibiti owo ni wọn fi n ra eroja ijagun fawon ologun, sibe, ko siyato, o wa pon dandan bayii lati pada si orisun wa, awa ọdẹ ti setan lati kun ijoba lowo, ti won ba le gba wa laaye o".
Bakan naa, nibi eto ohun, komisanna olopaa nipinle Osun, Fimihan Adeoye dupe pupo lowo awon ọlọde nipinle Osun fun ifowosowopo won lati dẹkun iwa odaran loniruuru ona kaakiri ipinle naa.
Adeoye, eni ti okan lara awon amugbalegbe re soju fun so pe opolopo aseyori ni won ti mu ki oun se nipase titu asiri awon amookunsika ti wọn n ba pade ninu igbo lasiko ti won ba n sode kaakiri loru.
Nibi eto ọhun ni won ti fun Araba Awo tiluu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuubon lami-eye fun ipa takuntakun ti baba naa n ko lori agbega asa ile Yoruba kaakiri agbaye.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment