Ẹ fura o! Wọn ti n ji 'Pata' l'Osogbo o

Owo ileese olopa ipinle Osun ti te Opeyemi Adeleke lori esun pe o ka pata ọmọge kan toruko re n je Gift.

Aago kan oru ọjọ Monde, ojo kokanlelogun osu kinni odun yii lowo tẹ Opeyemi, ọmọ ọdun metalelogun.

Agbegbe Agowande nilu Osogbo ni Opeyemi ti ji awotele naa ka.

Adajo majisreeti kan l'Osogbo, Mary Awodele si ti pase bayii pe ki won ju Opeyemi sewon titi di osu to n bo tidajo yoo tun waye lori esun ole jija ti won fi kan an.

No comments:

Post a Comment