Mo mọ aini awon eeyan mi, mo si ti setan lati dẹrin pẹẹkẹ wọn - Babayemi


iroyin/oselu

Dokita Dotun Babayemi ti egbe oselu Action Democractic Party (ADP) fa kale bayii lati dupo gege bii asofin ti yoo soju awon eeyan agbegbe Iwo-Orun Osun nile igbimo asofin agba orileede yii ti seleri lati mu aye gbẹdẹmukẹ fawon eeyan oun ti won ba le fi ibo won gbe e wọle.
Leyin ti gbogbo awon omo egbe oselu naa lati woodu aadofa to wa ni ẹkun naa fenuko lati lo Babayemi gege bii oludije ni dokita naa ni aini awon eeyan agbegbe ọhun ko sajeji si oun, lọgan loun yoo si bere ise toun ba jawe olubori.
O fi kun oro re pe gbogbo ibi ti bata ti n ta awon eeyan oun lẹsẹ ni oun yoo wa ojutu si, pelu iranlowo Olorun, bee loun yoo si sagbekale awon abadofin ti yoo mu idagbasoke ba awon eeyan oun, ipinle Osun ati orileede yii lapapo.
Ninu oro tire, oludije funpo gomina ninu egbe oselu naa lasiko idibo to koja, Alhaji Moshood Olalekan Adeoti ni egbe naa ye loriyin fun idibo abẹle alakoyawọ to se kaakiri ipinle Osun.
O wa rọ gbogbo awon eeyan agbegbe naa lati fowosowopo pelu egbe oselu ADP, ki won gbe Babayemi, eni to sapejuwe gege bii oludije to kaju e, wọle ninu idibo ti yoo waye lọdun to n bo.
Bakan naa ni alaga ADP l'Ọṣun, Ogbeni Toye Akinola so pe alaafia ni egbe ADP duro fun nipinle Osun, yoo si je itura fun awon araalu lati fi ibo won gbe gbogbo awon oludije ti egbe naa ba fa kale ninu idibo osu keji odun 2019 wole.

No comments:

Post a Comment