Esi idanwo WAEC ọdun yii ti pa awọn alatako iṣejọba Arẹgbẹṣọla lẹnu mọ - Kọla Ọmọtunde Young

iroyin/eto eko

Komisanna feto eko nipinle Osun, Alhaji Kola Omotunde Young ti ni idalare nla ni esi idanwo oniwe mewa WAEC to jade laipe yii je fun obitibiti ipa ti Gomina Aregbesola n sa lori igbedide eto eko nipinle Osun.


Lasiko ipade oniroyin kan ni Omotunde ti salaye pe ida aadorin ninu ogorun awon akekoo ti won sedanwo WAEC l'Osun lodun yii ni won gbegba oroke ninu eto isiro, nigba ti awon to din die ni ida ogota fakoyo ninu ede oyinbo.

O ni atupale esi idanwo naa lati odun metala seyin safihan pe iyato nla ti ba eto eko ipinle Osun pelu ohun to sele lodun yii eleyii to ni ko seyin bi ijoba Aregbesola se mu oro eto eko lokunkundun yato si owo yepere ti awon ijoba to ti koja l'Osun fi mu un.

Kola-Young ni idunnu nla lo je fun oun pe laarin awon omo ti won din die ni egberun lona ogun ti won joko sedanwo naa, idamerinlelaadota ninu ida ogorun lo yege ninu ede oyinbo ati imo isiro, eleyii to ni ko tii si iru e lati odun metala seyin nipinle Osun.

Gege bo se wi, "Ida meedogbon ninu ida ogorun awon omo ti won n sedanwo WAEC ko too di pe Aregbesola de ni won maa n yege, sugbon pelu igbiyanju ati ipinnu okan, a ti ni akosile ida merinlelaadota bayii. Ko si bojuboju nibe, nnkan ti gbogbo eeyan le loo yewo lori ero ayelujara ajo WAEC ni.

"Akitiyan wa lori fifi aaye ifimokunmo sile fawon oluko, atunto ileewe nipinle Osun, fifun awon omooleewe alakobere lounje ofe, opon imo, atawon nnkan miin tijoba se lo fun wa lanfaani nla yii".

Komisanna ni awokose rere nipinle Osun je bayii, o ti fiyun lelẹ, bee lo ti pa enu awon alatako ijoba Aregbesola mo nipa eto eko, ati pe ijoba ko nii dawo duro lori ise rere naa.

No comments:

Post a Comment