Atiku ni imọ kikun nipa eto ọrọ aje orilẹede yii ju Buhari lọ - Ọbasanjọ


iroyin /oselu

Oloye Olusegun Obasanjo ti so pe bii igba teeyan fee fi iku we oorun ni teeyan ba n gbe Alhaji Atiku Abubakar si egbe Aare Buhari nipa eto isakoso orileede yii.

Lasiko ti awon lookolooko lorileede yii tele Atiku, eni to fee dupo aare orileede yii labe asia egbe oselu PDP, lọ sodo Oloye Obasanjo nile re to wa nilu Abeokuta lo soro yii.

Obasanjo ni ohunkohun to wu ko maa bi oun ninu si Atiku to je igbakeji oun tele, oun ti dari ji i gege bii kristiani. O ni oun ti rii ninu iwa ati ise Atiku pe o ti yipada, o si ti di eda titun, eni to se e fokantan.

O so siwaju pe oun nigbagbo kikun ninuu ipa Atiku lati mu orileede yii goke agba to ba di aare nitori o je eni to ti saseyori nidi okoowo to se, bee lo niriri nipa nnkan to n lo nile ati loko, eleyii si fi oun lokan bale pe yoo se daada nijoba ju Aare Buhari to wa nibe lo.

Oloye Obasanjo wa ro Atiku lati mase yesẹ ninu akosile ofin orileede yii, ko gboju aagan si iwa jegudujera, ko mu oro awon odo ati obinrin lokunkundun, ko si sejoba alakoyawo nitori pe oun ni yoo jawe olubori gege bii aare orileede yii lodun to n bo.

No comments:

Post a Comment