Awon eeyan agbegbe IBO fariga, won lawon o fẹ Afolabi tawon kan fagidi fa kale

iroyin/oselu

Ifehonuhan n lo lowo bayii laarin awon eeyan agbegbe ijoba ibile Ifelodun, Boripe ati Odo-Otin nipinle Osun lori bi won se fa Onorebu Rasheed Olalekan Afolabi kale lati soju awon eeyan naa nile igbimo asofin apapo orileede yii.


Opin ose to koja la gbo pe Gomina Aregbesola ati akowe funjoba tẹle, Enjinia Sola Akinwumi pepade awon ti oro kan lagbegbe naa, won si kede pe Afolabi ni egbe APC yoo lo fundibo sile igbimo asofin apapo ti yoo waye lodun to n bo.

Lara awon oludije yooku ti won ti fi ife han lati dupo ohun tẹlẹ ni Alhaji Moshood Oluawo (MUSADEK), Architect Lekan Usman, Dokita Michael Olugbile, Bello Adegboyega Basheer ati komisanna foro iroyin, Onorebu Adelani Baderinwa.

Iyalenu loro naa je fun gbogbo won nitori se ni won n mura sile fun idibo abele, eleyii ti yoo mu akoyawo wa fun idibo asojusofin agbegbe naa.

Kia lawon alatileyin Musadek fariga, bee lawon agbaagba egbe ti won wa latibe pariwo pe ko ye ko ri bee, iyanje lo si maa n tu egbe.

Won ni ko seni ti ko mo pe egbe oselu ADP ni Afolabi sise fun lasiko idibo gomina to waye koja losu kesan odun yii, bee nii kii se eni to joloootọ si egbe APC rara.

Ogbeni Bello Adeleke ni igbese to lewu fun egbe oselu APC ni fifi agidi gbe Afolabi le awon eeyan lori nitori pe ko setẹwọgba ni woodu re, ka to sọrọ ijoba ibile to ti wa.

No comments:

Post a Comment