Asotele ti wa nipa iku baba ko too ku - Iyawo Baba Sala

iroyin/osere

Okan lara awon iyawo Apostle Moses Olaiya Adejumo, ti gbogbo eeyan mo si Baba Sala, Iyaafin Funmilayo Adejumo ti so pe o ti to odun meji seyin ti asotele ti wa lori ipapoda baba naa.


Nnkan aago mewa ale ana la gbo pe baba alawada naa jade laye ninu ile re nilu Ilesa leyin to lo odun merinlelogorin laye.

Iyaafin Funmilayo ni ninu ijo baba naa, C&S to wa ni Idasa nilu Ilesa ni asotele ti so pe bii idan ni iku baba naa yoo je, ko si seni ti yoo le mo tabi so nnkan kan nipa wakati ti yoo jade laye.

Obinrin yii ni nnkan aago mejo ale ana ni Baba Sala jẹun, leyin naa lo lọọ joko lori aga ni palọ, nibe ni baba naa wa to fi je Olorun nipe.

Nigba aye re, Baba Sala ni iranse Olorun lori ijo C&S, Idasa No1, Model Parish and Council District headquarters nilu Ilesa.

No comments:

Post a Comment