Lasiko ti ajo INEC n fun un ni iwe-eri gege bii olubori ninu idibo ati atundi ibo gomina to waye koja nipinle Osun, Oyetola ni oun mo riri ipa takuntakun ti tolori-telemu ko ninu aseyori oun.
Oyetola, nibi eto naa to waye ni gbongan ajo INEC to wa nilu Osogbo, so pe ise ribiribi ni ajo INEC, awon agbofinro atawon oniroyin se lasiko idibo naa, idi si niyen ti oun ko fi gbodo ja gbogbo won kule.
Leyin odun merin akooko isejoba oun, Oyetola ni ayo ni yoo je fawon eeyan ipinle Osun pe oun je gomina won. O si pe fun atileyin gbogbo eeyan fun aseyori isejoba rẹ.
Lara awon ti won wa nibi eto naa ni igbakeji gomina tuntun, Benedict Olugboyega Alabi atiyawo e, Onorebu Olubunmi Etteh, Adejare Bello, Omooba Gboyega Famodun, Onorebu Famurewa, Onorebu Salinsile ati bee bee lo.
No comments:
Post a Comment