Arufin ati ọlọkunrun ni Sanwoolu - Ambọde

Gomina ipinle Eko, Akinwumi Ambode ti so pe ti gbogbo eeyan ba n dide lati dupo gomina nipinle Eko, kii se iruu Jide Sanwoolu.

iroyin/oselu

Nibi ipade oniroyin kan to se laipe yii ni Ambode ti ni oun ko beru rara pelu bii awon lookolooko ninu egbe oselu APC nipinle Eko, to fi mo Asiwaju Bola Tinubu se ti fi atileyin won han gbangba si erongba Sanwoolu.

O ni oun setan lati fi eyin Sanwoolu bẹlẹ ninu idibo piramari ẹgbe naa nitori pe eni ti ilera re ko ba pe ko lee dupo gomina, gbangba si ni ẹri wa nilewosan Gbagada lori ilera Sanwoolu.

Bakan naa lo ni awon agbofinro orileede USA ti figba kan mu Sanwoolu ri lori esun pe o na ayederu owo dọla ni pati alẹ kan nibẹ.

O waa so fun awon alatileyin re lati mase mikan rara nitori oun ti setan lati na ọrọ naa bii owo pelu egbe oselu APC nilu Eko.

No comments:

Post a Comment