Won fesun kan Famoodun, alaga APC l'Osun, won lo ni oludije to n sise fun

Iwadi ti fi han bayii pe gbogbo oniruuru ogbon ti awon alakoso egbe oselu APC nipinle Osun n da lati lo ilana gbangba-lasa-ta (Direct Primary) fundibo piramari ti won yoo ti mu oludije funpo gomina ko seyin ona lati fi dandan gbe oludije kan wole tipatipa.


Atejade kan ti agbarijo awon oludije ninu egbe naa nipinle Osun (Coalition of Aspirants) nipase agbenuso won, Alhaji Kelani Abdulazeez fowosi salaye pe se ni alaga egbe naa, Omooba Gboyega Famodun, Onorebu Rasaq Salinsile ati Onorebu Segun Olanibi n da ijoba tiwon se ninu egbe naa.

Gege bo se wi, "Awon oloye merindinlogbon lo wa ninu eyi ti awon merindinlogun ti je igbimo tijoba ipinle, sugbon awon meta pere ni won n da nnkan se laije ki awon to ku mo nnkan kan, bee ni won si n fi ogbon ta egbe soko eru.

"Ero won ni lati lẹdi apo pọ mọ awon kan ninu awon alase ijoba (members of the cabinet), eleyii ti a mo pe o ni ọwọ Gomina Rauf Aregbesola ninu, lati fi dandan mu ki a lo ilana gbangba-lasa-ta (Option A4) lati fi yan eni ti yoo je oludije fegbe wa.

"Won pinnu lati lo ilana idibo yii leyin ti oniruuru iwadi ti won se fidi re mule pe jebete yoo gbe omo le won lowo ti won ba lo ilana pe kawon asoju (delegates) dibo nitori pe Alhaji Moshood Adeoti to je akowe ijoba ipinle Osun yoo fi eyin awon oludije to ku bẹlẹ.

"Eru won tubo po si nigba ti won tun rii pe ti awon ba lo ilana gbangba-lasa-ta ninu eyi ti awon oludibo yoo ti to seyin oludije ti won ba fe gan an, ida aadorin ninu ida ogorun awon oludibo ni yoo ba Adeoti lo, idi niyii ti won fi n sa gbogbo ipa won lati se magomago iwe akosile oruko awon omo egbe kaakiri ijoba ibile ogbon ati eria ofiisi.

"Opolopo oruko awon omo egbe oselu APC ni won ti yo kuro ninu iwe akosile egbe to ti wa lati odun 2014, won si ti fi awon ayederu oruko sibe, bee ni won ti bere sii te kaadi egbe l'Ekoo lati le fi te iwa wobia won lorun".

Atejade naa tun fesun kan Famoodun pe oun atawon isomogbe re ti bere sii te kaadi alalope (Permanent Voters Card, (PVC) eleyii ti won pinnu lati lo fun magomago lasiko idibo to n bo lojo kejilelogun osu kesan odun yii.

"Lati le mu keleyii rorun, ara erongba won ni lati ko ogunlogo awon eeyan ti won yoo ha awon ayederu kaadi omo egbe le lowo lati ipinle Eko atipinle Oyo lati fi dibo fun oludije ti won ba to si leyin.

"Mejilelogun lara awon osise ileese ajo eleto idibo (INEC) ti won rii pe won yoo fowosowopo pelu won ni won ti ko oruko won jo lati sise papo pelu awon to n bo lati olu ile egbe wa, bee ni won yoo lo awon osise ajo eleto idibo ipinle Osun (Osiec) gege bii awon alamojuto eto idibo ohun.

"Bakan naa ni Famodun atawon isomogbe re ti pinnu lati lo awon alaga pelu kanselo nijoba ibile kaakiri lati fi dunkoko mo awon oludibo lojo piramari naa, ki won si maa hale mo won lati dibo fun eni tawon alaga naa ba fe".

Egbe naa wa seleri pe mimi kan ko nii mi awon ninu ipinnu lati ri pe ife awon omo egbe lo fese mule, kii se ohun ti won fi agbara mu won lati se.

No comments:

Post a Comment