Taofeek ji baagi koko meji n'Ileefẹ, lo ba foju bale ejo


Taofeek Ogunsola ni won fesun kan pe o wonu oko okunrin kan ti won pe oruko re ni Agboọla Oorewole lojo kerin osu keje odun yii, to si ji baagi koko nla meji.

Ojo kinni osu keje odun yii nigbejo yoo te siwaju lori esun ole jija ti ileese olopaa ipinle Osun fi kan Taofeek eni odun mejilelogoji.

Nnkan aago kan osan, gege bi agbefoba to n gbo ejo naa, Inspekito Emmanuel Abdullahi se so funle ejo, ni Taofeek lo ji koko naa to wa labule Ogbaagba nitosi ilu Ileefe.

Abdullahi ni apapo owo  baagi koko mejeeji ti Taofeek ji gbe ohun je egberun lona aadorun naira, eleyii to nijiya nla labe abala kejilelogorin ati irinwo o din mewa ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Osun n lo.

Nigba ti won ka awon esun mejeeji ti won fi kan an, eleyii to nii se pelu fifi agidi wọnu oko-oloko ati ole jija si i leti, o ni oun ko jebi won.

Agbejoro re, Sunday Olagbaju ro ile-ejo lati faaye beeli sile olujejo, o seleri pe yoo fi awon oniduro sile, bee ni ko nii salo fun igbejo.

Ninu idajo re, Majisreeti Olalekan Ijiyode faaye beeli sile fun Taofeek pelu egberun lona ogorun naira ati oniduro kan ni iye kannaa.

O ni oniduro naa gbodo maa gbe larowoto ile ejo, bee lawon olopaa gbodo mo ile re. Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kinni osu kejo odun yii.

No comments:

Post a Comment