A ko nii faaye gba awon anikanjọpọn lati da wahala sile l'Osun - COYO



Agbarijopo egbe awon odo nipinle Osun, Coalition of Osun Youths Organisation pelu ifowosowopo egbe Development Advocacy Group (DAG) ti sekilo pe ko seni ti yoo fojuure wo enikeni to ba fee fi oro idibo gomina to n bo yii da wahala sile lonakona.

Lasiko iwode woorowo eleyii ti won bere lati orita Ayetoro nilu Osogbo titi de sekiteriati egbe oselu APC ni won so pe anikanjopon ni gbogbo awon oloselu ti won n pariwo pe apa ibikan lo ye ki gomina ti yoo gbapo lowo Gomina Aregbesola ti wa.

Adari egbe naa, Dokita Ademola Oyedokun so fawon oniroyin pe oro ti ko see gbo lasiko olaju yii ni kawon kan joko sibikan, ki won maa fowo lalẹ pe apa ibikan ni ki oludije ti wa laika boya o kunju osunwon tabi ko kunju osunwon si.

Oyedokun ni ara iwa awon ojelu ni igbese naa nitori pupo ninu awon ti won n pariwo naa ni won je agbalagba ti won n beru ohun ti ojoowaju won yoo je, ti won si n wons lati fi eni ti won yoo maa gbe gbogbo bukata won le lori sipo gomina.

O ni kii se ife awon araalu lo wa lokan awon oloselu ti won wa nidi oro naa, bee ni won ko ronu ona ti itesiwaju yoo fi tubo maa ba ipinle Osun leyin ise takuntakun ti Aregbesola ti fi odun mejo se.

Okunrin naa fi kun oro re pe se lo ye ki gbogbo awon eeyan, laika ti egbe oselu si, joko, ki won si ronu eni to kunju osunwon, to je olopolo pipe, to si le tese bo bata nla ti Gomina Aregbesola fee bo sile yii.

No comments:

Post a Comment