Alhaji Gboyega Oyetola ti so pe to ba je pe ooto laheso to n lo kaakiri ipinle Osun pe oun layanfe Gomina Aregbesola ninu idibo gomina to n bo ni, oun ko nilo lati se wahala boun se n se yii rara.
Lasiko ti Oyetola, eni to je olori osise lofiisi gomina ipinle Osun, loo fi foomu re sile lolu ile egbe oselu APC nilu Abuja lo ti ni iyalenu lo je fun oun pe awon kan le joko si kọrọ yaara won, ki won si maa so pe Aregbesola lo ni koun jade lati dije funpo gomina.
Oyetola ni odidi ogbon odun loun ti lo lenu ise aladani koun tun too wa lo odun mejo lenu isejoba, gbogbo awon iriri yii si ti fun oun lanfaani lati kunju osunwon gege bi eni to le jade dupo gomina l'Osun.
O ni aja to ba leni leyin lagbara lati pa ọbọ. "To ba jẹ pe se ni enikeni ti mi jade ni, se ni maa joko, ti maa si feyinti, sugbon ojoojumo ni mo n sise asekara lati je ki awon eeyan mo nipa erongba mi lati sin won, ara-ọtọ si ni ipolongo temi nitori ko sibi ti a de ti e ko nii ri ayo loju awon araalu".
O fi kun oro re pe ko si gomina to le se aseyori bii ti Aregbesola laise pe olori osise lofiisi gomina fowosowopo pelu e nitori olori osise ni enjinni to gbe ijoba ro, gbogbo iwolewode yii lo si fun oun lanfaani lati mo nipa isejoba daadaa.
Ni ti awon ti won n so pe ẹkun ibikan lo ye ki gomina ti wa, Oyetola ni oun ko fee soro pupo lori e sugbon oro elekunjekun ko si ninu iwe ofin ti egbe oselu APC n lo lorileede yii.
Oyetola waa seleri lati ro'ko mo awon ise takuntakun ti Gomina Aregbesola ti se sile l'Osun, kipinle Osun le maa gbadun isejoba to duroore siwaju sii.
No comments:
Post a Comment