Pelu bi idibo gomina ipinle Osun se n kanlekun bayii, egbe oselu Restoration Party ti kede Arabinrin Mercy Ayodele gege bii oludije ti yoo koju awon oludije latinu egbe oselu to ku ninu idibo naa.
Leyin idibo abele egbe oselu naa, eleyii to waye nilu Osogbo, ninu eyi ti gbogbo awon asoju egbe lati gbogbo ijoba ibile mokanlelogbon to wa nipinle Osun ti dibo ni alukoro apapo egbe RP lorileede yii, Onuiri Kingsley ti gbe asia egbe fun Ayodele lati je oludije egbe naa.
O fi kun oro re pe sise atileyin fun gbigbe obinrin kale funpo gomina je awokose rere fun awon egbe oselu to ku, nitori ipo obinrin ti kuro nile idana bayii, won ye leni to n se asiwaju.
O waa ro awon eeyan ipinle Osun lati fowo ti Ayodele leyin ko ba a le saseyori ninu idibo naa pelu ileri pe egbe oselu RP nikan lo ni erongba rere fawon araalu.
Bakan naa ni asoju ajo eleto idibo orileede yii, (INEC), gboriyin fun awon alakoso ati omo egbe oselu RP l'Osun fun bi won se seto idibo piramari naa, o si ni awokose ni idibo naa je fawon egbe oselu to ku.
Ninu oro idupe re, Arabinrin Mercy Ayodele ni iwuri nla lohun to sele naa je fun oun, bee lo ni ojo manigbagbe lojo naa yoo je ninu igbesi aye oun.
Gege bii obinrin rere loode ọkọ, Ayodele ni oun mo gbogbo ibi ti bata ti n ta awon obinrin lẹsẹ nipinle Osun, o si ti wa ninu ilakale eto loriisirisii toun ni lati rii pe igbe-aye irorun je tawon obinrin ati omode.
Alaga fun egbe oselu Restoration Party nipinle Osun, Alufaa Tosin Odeyemi fi idunnu re han si aseyori idibo abele naa, o si sapejuwe re gege bii ọwọ nla Olorun lati yọ awon eeyan ipinle Osun lowo iponju egbe oselu APC ati PDP.
O ni iyalenu ni oro egbe RP yoo je fawon eeyan ipinle Osun nitori pe awon yoo gbajoba ipinle Osun lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
No comments:
Post a Comment