VSDC ko ire wọ ipinlẹ Ọṣun; eto iranwọ lọna irọrun ni wọn mu wa


Ajo kan ti kii se tijoba, Visioned Skills Development Centre (VSDC) ti so pe eto iranwo owo tawon mu wa fawon eeyan ipinle Osun kii se eyi to ni ele ninu rara nitori erongba awon ni lati rii pe nnkan lo deede fawon eeyan ẹsẹkuku.

Alase ati oludari ajo naa, Apostle Isreal Emeka lo soro yii nigba to n ba awon oniroyin soro nibi eto itaniji kan ti won se fawon eeyan ipinle Osun eleyii to waye ni Atlantic Event Center nilu Osogbo.


Emeka ni ohun kansoso to n sakoba fun eto aabo to peye lorileede Naijiria ko seyin ainise lowo, paapaa laarin awon odo, idi si niyii ti ajo VSDC pelu iranlowo oja agbaye kan ti won n pe ni Social Exchange Market fi pinnu lati mu eto naa to awon eeyan lo.

O ni aimoye anfaani bee lo ti maa n wa sorileede yii tele sugbon to je pe awon anikanjopon kan ni won maa n daso bo o mole, idi niyi tawon ti won n ko owo naa jade fi pinnu lati lo awon iranse Olorun, yala kristieni tabi musulumi lati fi pin owo naa fawon eeyan kaakiri.

Apostle Emeka ni latigba ti won ti fowo si ajo oun, VSDC, gege bi okan lara awon ajo ti yoo sagbateru eto iranwo owo naa, loun ti n lo kaakiri lati ba awon eeyan soro pe ki won forukosile lati janfaani bantabanta naa. 

O fi kun oro re pe eeyan egberun kookan ni won yoo wa labe banki alabode kookan, mewa irufe banki naa ni yoo si wa nipinle Osun, bere lati egberun lona otalelugba o din mewa naira si milioonu mewa naira (#250,000 si #10,000,000) ni won yoo si maa fun awon to ba ti kunju osunwon fun eto iranwo ọhun.

Lara awon ise tawon araalu yoo lanfaani lati gba owo iranwo naa fun ni ise agbe, ise osin, okoowo, irinse fun ise-owo ati bee bee lo, awon adari ti won je asoju ajo naa kaakiri awon ijoba ibile ni won yoo si maa mojuto bi olukuluku awon to ba janfaani owo ọhun yoo se lo o.

O waa ro awon eeyan ipinle lati ri anfaani naa gege bii eyi ti Olorun ran si won, ki won gba foomu, ki won si se ohun gbogbo to ba tọ lori ẹ.

No comments:

Post a Comment