Idi ti mo fi maa n yinbon pa awon olopa ti mo ba ti loo jale - Micheal

Okan lara awon adigunjale ti won sose nilu Offa lojo karun osu kerin odun yii, Micheal Adikwu ti so pe ti oun ba le bo ninu eleyii, titi lai loun yoo tun maa pa awon olopaa nibikibi toun ba ti ri won.




Nigba ti Micheal n ba awon iko IRT soro lo ni ona ti won gba da oun duro lenu ise olopa nipinle Kwara lo mu koun pinnu lati maa gbesan lara awon olopa.

O ni eka SARS loun ti n sise tele ko too di pe won so pe oun mo bi awon afurasi adigunjale kan se salo logba ewon.

Micheal ni oro naa lo gbe oun kuro lenu ise olopa, idi niyen toun si fi maa n pa awon olopa nibikibi toun ba ti saaju idigunjale.

No comments:

Post a Comment