Igbo ni won ka mo Opeyemi lowo n'Ileefẹ, lawon olopa ba gbe e lo sile ejo
Ọpẹyẹmi Omilana, ẹni ọdun mejidinlogoji nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti gbe lọ sile ẹjọ majisreeti kan nilu Ileefẹ bayii latari pe ko ni awijare kankan lorii baagi igbo ti wọn ka mọ ọn lọwọ.
Ọjọ kẹfa oṣu karun ọdun yii la gbọ pe ọwọ tẹ Ọpẹyẹmi lagbegbe Mọọrẹ nilu Ileefẹ ni nnkan aago mọkanla aabọ alẹ.
Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi ṣalaye nile ẹjọ pe nigba ti wọn ka baagi igbo nla kan ọhun mọ olujẹjọ lọwọ, wọn beere ibi to ti ri ẹru ofin naa ṣugbọn ko ri nnkan kan wi.
Lẹyin ti wọn gba ọrọ lẹnu ẹ ni agọ ọlọpaa ni wọn taari ẹ lọ sile ẹjọ. Ọsanyintuyi ni iwa olujẹjọ naa lodi si abala irinwo o le ọgbọn iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Nigba ti wọn ka ẹsun ti wọn fi kan an sii leti, o ni oun ko jẹbi, bẹẹ naa ni agbẹjọro rẹ, Ben Adirieje rọ ile ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun un lọna irọrun pẹlu ileri pe ko nii sa fun igbẹjọ nitori yoo fi awọn oniduro to lorukọ silẹ.
Adajọ majisreeti naa, Ọlalekan Ijiyọde sọ pe ko lee si aaye fun beeli rẹ ayafi ki agbẹjọro rẹ kọ iwe wa nilana ofin.
O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Ọpẹyẹmi pamọ sọgba ẹwọn, o si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹfa ọdun yii.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment