Egberun mewa akekojade nijoba mi yoo maa pese ise fun lodoodun - K-rad


Oludije kan funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu APC, Barista Kunle Rasheed Adegoke, K-rad, ti so pe yoo rorun fun oun lati sejoba ipinle yii pelu ipile rere ti Gomina Aregbesola ti fi lelẹ.




Lasiko ti K-rad sabewo si olu ile egbe oselu naa nilu Osogbo lati fi akosile awon erongba re lori idagbasoke ipinle Osun han awon agbaagba ati adari egbe lo soro naa.

Okunrin agbejoro naa ni erongba oun lati dije funpo gomina ko seyin ife toun ni si awon araalu ati pe nibi ti Gomina Aregbesola tukọ isejoba ipinle Osun de loun yoo ti bere.

Gege bo se wi, 'gbogbo nnkan ti a nilo fun idagbasoke ipinle Osun lo ti wa nibi, o si rorun fun wa lati se awon nnkan yii nitori ipile rere ti Gomina Aregbesola ti fi lele. Ohun merin pato la fee mojuto; isodotun eto oro-aje, eto eko to ye kooro, awon ise akanse pelu awon ibudo asa ati nnkan isembaye.

"A gbodo gbokan kuro nibi owo to n wole lati odo ijoba apapo, a si le se eleyii nipa mimojuto oro ise agbe. Pelu ifowosowọpo awon araalu, o see se lati maa ri owo to to bilioonu mewa naira losoosu pa wole labenu nipinle yii.

"Nipase ise agbe yii naa la ti maa gba awon akekoojade egberun lona mewa lodoodun, eleyii yoo si mu ki airise dohun igbagbe, ti ounje yoo si po yanturu.

"A maa gbe awon ibudo idako bii ti aye Awolowo dide, a ni ilẹ daada, ko si si nnkan to buru ti awon eeyan ipinle Eko ati Ogun ba wa n ra ounje latipinle Osun.

"Olumirin waterfall ati Erinjesa waterfall wa nipinle wa, ti a ba samojuto awon ibudo eleyii ti ko si iru e niha iwo oorun orileede yii, owo yanturu ni yoo maa wole latibe".

Ninu oro re, alaga egbe oselu APC, Omooba Gboyega Famoodun dupe lowo Kunle Adegoke fun ife to ni si oro ipinle Osun, o wa seleri pe ko nii si ojusaju rara, owo kannaa lawon yoo si fi mu gbogbo awon oludije.

No comments:

Post a Comment