Olori osise loofisi gomina ipinle Osun, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetola ti ni erongba oun lati dije dupo gomina ipinle Osun kii se eyi to mu agidi tabi aigbodo ma se lowo bikose ife ti oun ni si awon araalu lati je ki won maa gbadun awon nnkan meremere tijoba Gomina Aregbesola ti fi ipile re lele l'Osun siwaju sii.
Oyetola, lasiko to n ba awon oniroyin soro leyin to fi erongba re han nile egbe oselu APC l'Osogbo pe oun fee dije salaye pe Olorun lo n gbe eda depo laye, kii se agbara.
O ni niwon igba ti Olorun to je pe Olorun lo seleri fun oun gege bii inagije ikọ ipolongo oun "Ileri Oluwa", oun nigbagbo pe o di dandan ki ileri naa wa simuse, ki oun si di gomina ipinle Osun lojo kejìlelogun osu kesan odun yii.
Oyetola ni awon eka mefa otooto ti isejoba Gomina Aregbesola duro le lori loun yoo tubo maa sise le lori nitori pe ko si asadanu ninu awon agbekale naa.
O waa seleri lati mu igbe aye rorun siwaju sii fawon osise ijoba, o ni gbogbo gbese owo osu to wa nilẹ pata ni Aregbesola yoo yanju ko too di pe isejoba re yoo kogba wole ati pe awon onise owo pelu awon iyaloja yoo gbadun isejoba oun dọba.
No comments:
Post a Comment