Ileese olopa ipinle Osun ti bere iwadi lori obinrin alaboyun kan ti won ba oku e lagbegbe kan nilu Owode-Ede.
Idaji oni lawon eeyan agbegbe naa dede ba oku alaboyun ohun legbe igbo rusurusu kan nibe.
Ko seni to le so ni pato ohun to sele si obinrin alaboyun naa nitori ko dabi eni pe won yo ohunkohun ninu eya araa re, bee ni ko si oju apa laraa re.
Sugbon awon olopa nilu Ede ti gbe oku naa lo sileewosan Cottage nilu Ede, bee ni won ti bere ise lati le ri awon molebi e.
No comments:
Post a Comment