Idagbasoke yoo wa nipinle Osun ti awon ọdọ ba ti niṣẹ gidi lọwọ - Ogunbiyi
Oludije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu PDP, Dokita Akin Oyebiyi ti seleri pe nipase ipese ise gidi fawon ọdọ nisejo oun yoo fi mu idagbasoke ti ko legbe wo ipinle Osun.
Lasiko abewo to se silu Ifetedo nijoba ibile Guusu Ife ati Ila-Oorun ni Ogunbiyi ti so pe oniruuru nnkan alumoni ni Olorun fi jinnki Ife, eleyii to ni o je anfaani nla fawon eeyan ipinle Osun.
Ogunbiyi ni gbogbo nnkan oro-aje tipinle Osun nilo wa ninu ilu Ife, oun si ti pinnu lati tun ipinle Osun so bii igba ti oun ba le lanfaani lati di gomina ipinle Osun ati pe riro awon odo lagbara pelu ise to see ti moni ni yoo ran erongba yii lowo.
O ni gbogbo awon nnkan amayederun to ye kawon eeyan agbegbe naa maa gbadun sugbon ti ko tii te won lowo loun yoo koko mojuto nitori oun mo isepataki Ileefe nipinle Osun.
Ninu oro asaaju kan to gba Ogunbiyi lalejo nilu Ifetedo, Onorebu Joel Oyeyemi ati alaga egbe nijoba ibile naa, Alhaji Remi Arogundade, won fi idunnu won han si gbogbo igbese oludije naa latigba to ti fi erongba re han, bee ni won si jeje atileyin won fun un.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment