Ona kansoso lati san esan ise rere fun Aregbesola ni ki APC wole l'Osun - Saka Layonu
Dokita Ismail Saka-Layonu ti so pe ona kansoso fawon eeyan ipinle Osun lati san esan oniruuru ise rere ti Gomina Aregbesola ti se ni ki egbe oselu APC rowo mu ninu eto idibo gomina to n bo yii.
Lasiko ti Layonu, eni to je agbejoro agba lorileede yii loo so erongba re lati dije funpo gomina ipinle Osun fawon agbaagba egbe APC lo salaye pe ara meriiri lawon nnkan tipinle Osun n foju ri labe isejoba Aregbesola lati odun bii mejo to ti de ori aleefa.
O ni ohun to nira fawon ijoba ti won ti wa saaju e lati se ni Aregbesola n se pelu iberu Olorun ati ife awon araalu, idi si niyii to fi ni awon eeyan ipinle Osun gbodo fi imoore won han sii nipa gbigbaruku ti oludije ti egbe oselu APC ba gbe kale lati rii pe o jawe olubori ninu idibo ohun.
Layonu ni oun ti setan lati mọ le ipile rere ti Ogbeni Aregbesola ti fi lelẹ l'Osun, oun yoo si tun se atunse gbogbo ibi to ba ku die kaato nigba ti oun ba gba eeku ida isakoso lowo e.
O fi kun oro re pe tolori telemu ni yoo ri se ninu isejoba oun niwon igba ti kaluku ba ti tepa mose pelu otito inu nitori pe ko nii si aaye fun imele tabi fifi ise jafara nipinle Omoluabi.
Ni ti awon odo, Layonu ni gbogbo ipa nijoba oun yoo sa lati rii pe awon ọdọ wulo ki igbelaruge ba le ba ipinle Osun.
O waa ro awon eeyan lati fi ibo won gbe oun wole nitori awon iriri oun yoo ran ipinle Osun lowo pupo.
Omooba Gboyega Famodun to je alaga egbe APC l'Osun waa jeje pe ọwọ kannaa lawon yoo fi mu gbogbo awon oludije nitori pe aparo kan ko ga ju ekeji lo.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment