Emi ni mo kunju osunwon julo lati gbapo lowo Aregbesola - Onorebu Lasun Yussuff

Igbakeji abenugan ile igbimo asofin apapo orileede yii, Onorebu Lasun Sulaiman Yussuff ti so pe ti a ba n soro nipa iriri ninu oselu ati jije olooto si egbe, oun ta gbogbo awon oludije to ku ti won n ferongba han lati di gomina ipinle Osun yo.



Nilu Osogbo ni asofin yii ti soro naa ni sekiteriati egbe oselu APC nigba to loo fi erongba re han lati dije funpo gomina nipinle Osun ninu eto idibo ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii.

Lasun ni oun ni anfaani lati de ipo toun wa lowolowo bayii ninu oselu nitori pe oun duro ninu egbe oselu APC laiyese ati laika oniruuru ipenija toun ti dojuko lati nnkan bii odun meta seyin si.

O ni opolopo awon ise ti Gomina Aregbesola se nipinle Osun ni won je amuyangan, ti oun yoo si te siwaju ninuu won. Lara awon ise naa ni eto O'Yes ati kiko awon ileewe nlanla fawon akeko kaakiri nipinle Osun.

Lasun fi kun oro re pe oniruuru eto loun ni nipamo fun idagbasoke gbogbo awon eeyan, ati onile, ati alejo ti won wa nipinle Osun.

O ni oun yoo mu igbelaruge ba oro ise agbe eleyii ti yoo mu ki owo ti yoo ma wole labenu rugogo sii.

Nigba to n ki Onorebu Lasun kaabo, alaga egbe oselu APC nipinle Osun, Omooba Adegboyega Famodun ni ohun to se pataki fun gbogbo awon oludije lati ni lokan ni pe enikansoso ni egbe yoo fun ni tikeeti lati dije.

Famodun ni ko seni ti ko mo ipa pataki ti asofin naa n ko fundagbasoke egbe, o waa fi da gbogbo won loju pe idibo abele alakoyawo lawon yoo se lati mu oludije ninu egbe naa.

No comments:

Post a Comment