Iroyin ti a gbo bayii fi han pe awon fulani darandaran ti ji pasito ijo Methodist kan nilu Osogbo, Very Rev Kayode Akande gbe pelu awon omo ijo meji miin nirole oni.
Ibi ipade kan nilu Ile Ogbo la gbo pe awon omo ijo naa mejo ti n bo ninuu moto meji, bi won se de ilu Telemu loju ona Iwo si Osogbo ni nnkan aago meje alẹ la gbo pe awon fulani ti won dihamora ogun naa da won duro.
Won wo Pasito Akande, Ogbeni Bankole to je enjinia ati Alagba Omodunbi sokale ninuu moto, won si gbe won gba ona inu igbo lo.
Awon marun to seku ni won pe awon araale, ti won si lo fi isele naa to awon olopa leti.
Komisanna olopa l'Osun, Adeoye Fimihan ni loooto nisele naa, bee lawon olopa si ti ya lo sinu igbo naa bayii lati sawari awon eeyan ohun.
No comments:
Post a Comment