Milioonu lona ogun naira lawon fulani n beere lowo awon molebi pasito ti won ji gbe
Iroyin to te wa lowo bayii ti fidi re mule pe awon fulani darandaran ti won ji pasito ijo Methodist pelu awon omo ijo meji gbe nitosi Osogbo lale ana ti beere fun milioonu lona ogun naira bayii ki won to le tu won sile.
Komisanna foro akanse ise, to tun je alarina laarin ijoba ipinle Osun atawon eya miin, Onorebu Mudashiru Toogun lo fidi oro naa mule lori redio laipe yii.
A oo ranti pe laago meje ale ana Sannde lawon fulani naa da Very Rev. Kayode Akande, Enjinia Bankole ati Pa Omodunbi lona labule Telemu loju ona Iwo si Osogbo, ti won si gbe awon meteeta wonu igbo latigba naa.
Ni bayii, okan lara awon oludije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe PDP, Akin Ogunbiyi ti ro ileese olopa ipinle Osun lati tete gbe igbese ti awon meteeta yoo fi di awari laini ifarapa kankan.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment