Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti fi owo re sọya pe laipe ni owo yoo te awon fulani ti won ji alufa ijo Methodist atawon omo ijo meji miin gbe loju ona Iwo si Osogbo.
Lasiko ti Aregbesola n gba awon asoju African Development Bank (AfDB) lalejo nile ijoba lo ti ni ipinle Osun je okan pataki lara awon ipinle ti aabo ti wa fun emi ati dukia awon araalu.
O ni iyalenu lo je pe awon onisolenu kan hu iru iwa to le ta epo si ẹri rere tipinle Osun ti ni latigba tisejoba oun ti de ori aleefa.
Aregbesola waa so pelu idaniloju pe laipe yii ni Very Rev. Kayode Akande, Enjinia Bankole ati Pa Omodunbi yoo gba itusile won laifarapa, bee ni owo yoo te awon ajinigbe naa lati foju winna ofin.
A oo ranti pe laago meje ale ojo Sannde to koja ni awon fulani darandaran da moto awon meteeta yii duro labule Asamu, ti won si ko won wonu igbo lo leyin ti won gba owo ati foonu won tan.
No comments:
Post a Comment