Dokita Akin Ogunbiyi to je oludije funpo gomina ipinle Osun labe egbe oselu PDP ti seleri fawon osisefeyinti pe gbogbo iya won ni yoo lo sokun igbagbe ni kete toun ba ti di gomina ipinle Osun.
Ilu Ikirun nijoba ibile Ifelodun ni Ogunbiyi ti soro yii lasiko to sabewo si won nibe. O ni gbogbo ẹtọ awon osisefeyinti ohun ni won yoo ri gba, bee lo ni awon talaka ti won n fomije funrugbin bayii yoo rerin laipe.
O ni oun ni imolara aini ati osi to n ba awon eeyan finra lowolowo labe isakoso egbe APC, o ni oun gege bii eni to n dari egbeegberun awon osise mo ona lati se koriya fawon osise nitori pe oogun alaaru ko gbodo gbe.
Ogunbiyi ni ibasepo to dan monran yoo wa laarin oun atawon osise ijoba nipinle Osun, loorekoore ni won yoo maa gbowo won, bee ni gbogbo ajemonu won ko nii ni idiwo rara.
O waa fi da awon eeyan ilu Ikirun loju je digbi loun wa ninu ipinnu oun lati dupo gomina ipinle Osun ati pe ko si ooto ninu aheso to n lo kaakiri pe oun ti jawo ninu erongba naa.
No comments:
Post a Comment