Komisanna foro okoowo, ileese ati alajeseku nipinle Osun, Onorebu Ismaila Adekunle Jayeoba-Alagbada ti so pe irorun tun ni irinajo awon ti won ba fee wa se odun itunu aawe nipinle Osun atawon ipinle to yii ka yoo je lodun yii nitori pe oko ojuurin ofe ti wa nile fun won.
Ninu atejade kan ti Alagbada fi sita lo ti salaye pe gege bii ise Gomina Rauf Aregbesola, oko ojuurin yoo gbe awon eeyan naa wa latipinle Eko saaju ojo odun, bee ni yoo tun da won pada leyin odun laigba owo kankan lowoo won.
Gege bo se wi, Tosde, ojo kerinla osu kefa ni oko ojuurin naa yoo gbera ni Iddo Terminus nipinle Eko laago mewa aaro, bee ni yoo gbe won pada silu Eko lojo Monde, ojo kejidinlogun osu kefa yii kannaa.
Alagbada ni "a fee lo asiko yii lati so fun awon omobibi ilu Osun ti won n gbe nipinle Eko, Ogun ati Oyo pe ijoba wa, gege bi a se maa n se, tun ti seto oko ojuurin ofe sile fun won saaju ati leyin odun itunu aawe.
"Eto yii wa lati le je ki won lanfaani lati waa ba awon ololufe atawon araale won se odun pelu inu didun laisi ironu owo ọkọ nibẹ".
Komisanna wa ro gbogbo awon ti won n bo nile lati lo asiko naa sabewo si awon oniruuru ise akanse tijoba ipinle Osun ti se kaakiri fundagbasoke ipinle Osun.
No comments:
Post a Comment