Ikunle abiamo o! E wo bi reluwe se te agunbaniro yii pa l'Eko

Lagbala iroyin la ti gbo pe okan lara awon agunbaniro obinrin ti won n sin orileede baba won nipinle Eko ti padanu emi re bayii. 
Se la gbo pe omobinrin ohun ti won pin pelu ileese kan nijoba ibile agbegbe Ikeja fi okun ti won fi ma n gbo orin (earpiece)  si eti re mejeeji lasiko to n koja loju ona reluwe to wa ni Ikeja eleyi ti ko je ko gbo pe reluwe n sare bo.
Meta ninu ika-owo omobinrin yii la gbo pe o koko run womuwomu, to si farapa pupo ki won too yara gbe lo si osibitu LASUTH sugbon nigba ti yoo fi di ale ojo naa, o ti jade laye.

No comments:

Post a Comment