Inu osu kefa odun yii ni odun merin ti ofin egbe APC la kale lati satunyan awon adari miin yoo pe sugbon awon kan ninu awon agbaagba egbe naa so pe ki won si yonda Oyegun lati wa nibe di odun to n bo.
Idi tawon eeyan ohun fi so bee ni pe didibo yan awon asaaju miin fegbe ohun le da wahala sile eleyii to le sakoba fun anfaani egbe ohun ninu eto idibo apapo odun to n bo, o si dabi eni pe Aare Buhari naa fowo si oro yii.
Sugbon latigba ti won ti daba naa ni awon kan ninu egbe, paapa julo awon alatileyin Tinubu ti n lera, won ni awon ko ni gba, afi dandan ki Oyegun maa lo ninu osu kefa, koda, awon kan ti fori le kootu nitori oro naa.
Amo sa, iwadi ti je ko di mimo pe okan pataki lara idi ti won fi n se bee ni pe won ko fe ki Oyegun wa nipo alaga nigba ti eto idibo abele lati mu eni ti yoo dije funpo gomina ninu egbe naa l'Osun yoo ba waye losu keje odun yii.
Gege bi omo egbe APC kan lati Ila Oorun Osun, Ogbeni Akinade Rufus se so, niwon igba ti ko ti si ibasepo to dan moran laarin Tinubu ati Oyegun, yoo nira fun ife okan Tinubu lati wa simuse nipinle Osun.
O ni "Se e mo pe Asiwaju Tinubu ti pa lase fun gomina wa lati sa gbogbo ipa re lorii bi Alhaji Gboyega Oyetola yoo se di gomina ipinle Osun sugbon won mo pe o maa le die ti Oyegun ba le wa nibe gege bii alaga.
"Idibo abele nikan lo le gba wa gege bo se sele nipinle Ondo, Oyegun ko si nii faaye sile fun magomago, ife okan awa omo egbe lo maa fee se, bee lawon to maa ran wa ko nii gbabode, idi niyen ti won fi n wa gbogbo ona lati le Oyegun kuro nibe losu kefa ka too dibo abele.
"Olorun nikan lo le saanu wa l'Osun nitori a gbodo kiyesara ki nnkan to sele lasiko idibo Seneto ojosi ma baa tun sele, oselu ti koja kenikan joko si Eko, ko maa dari ero okan wa l'Osun, mo saa mo pe ohun gbogbo a loju laipe".
No comments:
Post a Comment