Lagbala iroyin la ti gbo pe Oba Orin, Dokita Saidi Osupa lo si ilu Efon-Alaaye lati loo gbadura nibi oroori oludasile ijo CAC lagbaye, Apostle Ayodele Babalola.
Iyalenu lo je fun gbogbo awon olujosin lojo naa nigba ti Osupa dede yo sibe. Moto merin la gbo pe o tele Oba Orin yii lojo naa.
Bo se debe lo beere pe ibo gan an ni won sin Apostle Babalola si, bi won se mu un debe la gbo pe o Kunle segbe saare yii to si gbadura kikankikan.
Ko pe ti okiki abewo Saidi ohun fi gba gbogbo ilu Efon Alaaye kan, bayii lawọn ololufe re n ro girigiri lo sori oke naa lati foju gan an ni Saidi.
No comments:
Post a Comment