E fi oselu etanu sile, e fiwa jo Aregbesola - Akere


Bi orisirisi awon oludije se n gbaradi lati dupo gomina ipinle Osun bayii, komisanna tele foro iroyin, Oluomo Sunday Akere ti ro gbogbo won lati yago fun oselu etanu, ki won si fi ooto so nnkan ti won ni lokan fawon araalu.



Ilu Osogbo ni Akere ti soro naa laipe yii.
O ni ki awon oludije yago fun iwa imotaraeni nikan, sugbon ki won je ki ife awon araalu gbile lokan won.

Akere ni ko gbodo si oro tabi iwa to le da omi alaafia tipinle Osun n gbadun re lowolowo bayi ru, bee ni konikaluku gbajumo eto tie.

O wa ro awon oludibo lati mase ta eri okan won fawon jegudujera, ki won fojusile lati yan asiwaju to dara eleyii ti Gomina Aregbesola ti fi apere re lele nipase oniruuru aseyori to ti se l'Osun.

No comments:

Post a Comment